1 line
585 B
Plaintext
1 line
585 B
Plaintext
\v 35 Jesu dáhùn nígbà tí ó ń kọ́ ni nínú tẹ́ḿpílì, ó wípé, “Èéṣe tí àwọn olùkọ́ òfin fi wí pé Kristi ní ọmọ Dáfídì? \v 36 Dáfídì tìkára rẹ̀, nípa Ẹ̀mí Mímọ́ sọ̀rọ̀ wí pé, “ ‘Olúwa sọ fún Olúwa mi pé,“Jókòó ní ọwọ́ ọ̀tún mi, títí èmi yóò fi sọ àwọn ọ̀tá rẹ di àpótí ìtìsẹ̀ rẹ.' \v 37 Dáfídì tìkára rẹ̀ pè é ní ‘Olúwa,’ Báwo ni Olúwa tún ṣe lè jẹ́ ọmọ Dáfídì?” Ọ̀pọ̀ ènìyàn sì fi ayọ̀ gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀. |