yo_php_text_ulb/03/12.txt

1 line
529 B
Plaintext

\v 12 Kìí ṣe pé mo ti gba àwọn nǹkan wọ̀nyí, tàbí pé mo ti di pípé. Ṣùgbọ́n èmi ńlàkàkà kí èmi kí ó le ṣe àrígbámú ohun tí Krístì Jésù torí rẹ̀ gbámimú. \v 13 Ẹ̀yin ará, èmi kò rò pé èmi tìkara mi ti ṣe àrígbámú rẹ̀. Ṣùgbọ́n ohun kan ni o: mò ń gbàgbé ohun tí ó ti bọ́ sẹ́yìn mo sì ń nàgà wo ohun tó wà lọ́ọ̀ọ́kán. \v 14 Mò ń lépa àfojúsùn náà láti le gba èrè ìpè gíga ti Ọlọ́run nínú Krísti Jésu.