yo_php_text_ulb/03/08.txt

1 line
810 B
Plaintext

\v 8 Kódà, nísinsìnyí mo ka ohun gbogbo kún àdánù nítorí ìmọ̀ Jésù Krístì Olúwa mi níye lórí ju ohun gbogbo lọ. Nítorí Rẹ̀ mo ti da ohun gbogbo sí ààtàn. Mo kà wọ́n sí ẹ̀gbin kí èmi kí ó le fi Krístì ṣèrè jẹ. \v 9 kí á sì lè rí mi nínú Rẹ̀. Èmi kò ní òdodo ti ara mi láti inú òfin. Kàkà bẹ́ẹ̀, òdodo mi jẹ́ èyí tí ó wá láti ipasẹ̀ ìgbàgbọ́ nínú Krístì, òdodo ti ó wá láti ọdọ Ọlọ́run tí ó fìdí múlẹ̀ nínú ìgbàgbọ́. \v 10 Ǹjẹ́ nísinsìyí èmi fẹ́ mọ̀ Ọ́ àti agbára àjíǹde Rẹ̀ àti ìfarakínra àwọn ìjìyà Rẹ̀. Mo fẹ́ kí á yí mi padà sínú ìrísí ikú Rẹ̀, \v 11 kí èmi kí ó le ní ìrírí àjíǹde kúrò láàrin àwọn òkú.