yo_php_text_ulb/02/25.txt

1 line
635 B
Plaintext

\v 25 Ṣùgbọ́n mo rò pé ó yẹ kí n rán Ẹ̀páfródítù padà sí yín. Arákùnrin mi ni, alábàáṣiṣẹ́pọ̀ mi ni, akẹgbẹ́-ọmọ-ogun ni pẹ̀lú mi, bẹ́ẹ̀ sì ni ó jẹ́ ìráńṣẹ́ yín tí ó ń mójútó àwọn àìní mi. \v 26 Nítorí tí ọkàn rẹ̀ pòrurù gidi gan, ó sì ń jarán láti wà pẹ̀lú yín nítorí tí ẹ gbọ́ pé ara rẹ̀ kò yá. \v 27 Lóòótọ́ ni pé ó ṣe àìsàn dé ojú ikú. Ṣùgbọ́n Ọlọ́run ṣàánú fún un, kì í sì ṣe fún òhun nìkan, ṣùgbọ́n fún èmi náà, kí ìbànújẹ́ mi má baà peléke síi.