yo_php_text_ulb/02/28.txt

1 line
485 B
Plaintext

\v 28 Nítorí náà ó yámilára láti rán an sí yín, pé kí ẹ̀yin kí ó le yọ̀ nígbà tí ẹ bá rí i, kí ọkàn mi sì lè fúyẹ́. \v 29 Ẹ kí Ẹ̀páfródítù káàbọ̀ nìnú Olúwa pẹ̀lú ayọ̀. Ẹ máa bu ọlá fún àwọn ènìyàn bíi tirẹ̀. \v 30 Nítori iṣẹ́ Krístì ni ó fi fẹ́ẹ̀ kú. Ó fi ẹ̀mí rẹ̀ wéwu láti sìn mí àti láti dí ààyè ohun tí ẹ̀yin kò lè mójútó nípa iṣẹ́-ìsìn yín sí mi.