yo_php_text_ulb/02/14.txt

1 line
584 B
Plaintext

\v 14 Ẹ máa ṣe ohun gbogbo láìsí ìkùnsínú tàbí àríyànjiyàn. \v 15 Ẹ hùwà báyìí kí ẹ̀yin kí o le di aláìléèéri àti olótítọ́, àwọn ọmọ Ọlọ́run tí kò lábàwọ́n. Ẹ hùwà báyìí kí ẹ̀yin kí o le tàn bíi ìmọ́lẹ̀ nínú ayé, láàrin ìran tí kò tọ́ tí iyè wọn sì ti ra. \v 16 Ẹ di ọ̀rọ̀ ìyè mú ṣinṣin kí èmi kí ó le nídìí láti ṣògo lọ́jọ́ Krístì. Nítorí nígbà náà ni èmi yóò mọ̀ pé èmi kò lépa lásán bẹ́ẹ̀ sì ni n kò ṣe làálàá lásán.