\v 25 Pẹ̀lú àrídájú ohun kan yìí, mo mọ̀ pé èmi yóò wà pẹ̀lú yín síi fún ìtẹ̀síwájú yín àti ayọ̀ yín nínú ìgbàgbọ́. \v 26 Kí ẹ̀yin kí ó lè ní ìdí síi láti yangàn nínú Krístì Jésù láti ipasẹ̀ mi nígbàtí mo bá tún tọ̀ yín wá. \v 27 Kìkì pé kí ẹ̀yin kí ó má gbé ìgbé-ayé yín ní ìbámu pẹ̀lú ìhìnrere Krístì, tóbẹ́ẹ̀ tí ó fi jẹ́ pé bóyá mo wá wò yín tàbí n kò wá, èmi yóò lè máa gbọ́ nípa yín, pé ẹ̀ ń dúró ṣinṣin pẹ̀lú ẹ̀mí kan, ẹ sì ń lépa papọ̀ fún ìgbàgbọ́ ìhìnrere náà pẹ̀lú ọkàn kan.