adesinaabegunde_yo_php_text.../01/03.txt

1 line
487 B
Plaintext

\v 3 Mo dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run mi ní gbogbo ìgbà tí mo bá rántí yín. \v 4 Ní gbogbo ìgbà tí mo bá ń gbàdúrà fún gbogbo yín, tayọ̀tayọ̀ ni mo fi ń gbàá. \v 5 Mo dúpẹ́ fún bí ẹ ti ṣe alábàpiń nínu ìhìnrere náà láti ìbẹ̀rẹ̀ títí di ìsinsìnyí. \v 6 Mo ní ìgboyà ohun kan yí, pé Ẹnití ó ti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ rere nínú yín yíò tẹ̀síwájú láti yanjú rẹ̀ títí di ọjọ́ Jésù Krístì.