adesinaabegunde_yo_mrk_text.../10/32.txt

1 line
795 B
Plaintext

\v 32 Wọ́n wà lójú ọ̀nà wọ́n ńlọ sí Jèrúsálẹ̀mù, Jésù sí ńlọ níwájú wọn. Ẹnú ya àwọn ọmọ ẹ̀yìn, àti àwọn tí ò ǹtẹ̀le wọn lẹ́yìn ni ẹ̀rù síì ńbà. Lẹ́yìn náà Jésù mú àwọn méjìlá sí ẹ̀gbẹ́ kan ó sì bẹ̀rẹ̀ sí sọ fún wọn ohun tí yóò sẹlẹ̀ sí òun ní kòpẹ́kòpẹ́. \v 33 "wòó, àwa ńgòkè lọ sí Jèrúsálẹ̀mù, a ó sì fi ọmọ ènìyàn lé àwọn olórí àlùfáà àti àwọn akọ̀wé lọ́wọ́. Wọn ó dáa lẹ́bi ikú wọn ó sì fi lé àwọn kèfèrí lọ́wọ́. \v 34 Wọn ó fi se ẹlẹ́yà, wọn ó tu itọ́ sí lára, wọn ó nàá pẹ̀lú ẹgba, wọn ó sì paá. Sùgbọ́n lẹ́yìn ọjọ́ kẹ̀ta yó dìde