adesinaabegunde_yo_mrk_text.../07/17.txt

1 line
726 B
Plaintext

\v 17 Ní àkókò yìí, nígbàtí Jésù kúrò lọ́dọ́ àwọn ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn náà tí Ó sì wọ inú ilé, àwọn ọmọẹ̀yìn Rẹ̀ bií léèrè ìbéèrè lórí òwe náà. \v 18 Jésù dá wọn lóhùn wípé, "Ẹ̀yin kò tún tíì lóye èyí náà ni bíí? Sé ẹ kò tíì ri pé kòsí ohunkóhun láti òde àgọ́ ara ènìyàn tí ó le sọ ènìyàn di aláìmọ́ nígbàtí ó báwọ inú ènìyàn, \v 19 nítorípé kò le wọ inú ọkàn lọ, sùgbọ́n ó ń lọ sí inú ikùn ènìyàn tí yíó sì gba ibẹ̀ di ohun tí a ya ìgbẹ́ rẹ̀ sí ilé ìyàgbẹ́?" Jésù sọ gbogbo ohúnjẹ di mímọ́ pẹ̀lú gbólóhùn ọ̀rọ̀ yìí.