adesinaabegunde_yo_mrk_text.../12/20.txt

1 line
532 B
Plaintext

\v 20 Àwọn arákùnrin méje kan wà; èyí tí ó dàgbà jùlọ gbéyàwó, ó sì kú ní àìlọ́mọ. \v 21 Arákùnrin rẹ̀ kejì ṣú obìnrin tí ó fi sílẹ̀ lópó, òun pẹ̀lú tún kú láìbímọ. Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni arákùnrin kẹta. \v 22 Àwọn méjèèje kò sì fi ọmọ sílẹ̀, Ní ìkẹyìn gbogbo wọn, obìnrin náà kú pẹ̀lú. \v 23 Ǹjẹ́ ní àjíǹde, nígbà tí wọ́n bá jíǹde, aya ta ni yóò ha ṣe nínú wọn? Àwọn méjèèje ni ó sá ni ní aya?”