adesinaabegunde_yo_mrk_text.../16/14.txt

1 line
530 B
Plaintext

\v 14 Jésù sì tún farahàn fún àwọn mọ́kànlá bí wọ́n tí ń jẹun lórí tábìlì, ó sì bá wọn wí fún àìgbàgbọ́ àti líle àyà wọn, nítorí wọn kò gba àwọn tí ó kọ́kọ́ rí i, lẹ́yìn tí ó jí dìde gbọ́. \v 15 Ó sọ fún wọn pé, "Ẹ lọ sí gbogbo ayé kí ẹ lọ wáásù ìhìnrere fún gbogbo ẹ̀dá. \v 16 Ẹnikẹ́ni tí ó bà gbàgbọ́ tí a sì baptìstì rẹ̀ ni a ó gbàlà, àti ẹnikẹ́ni tí kò bá gbàgbọ́ a ó dá a lẹ́jọ́.