adesinaabegunde_yo_mrk_text.../14/06.txt

1 line
569 B
Plaintext

\v 6 Ṣùgbọ́n Jesu wípé, "Ẹ jọ̀wọ́ rẹ̀. Kílódé tí ẹ̀yin fi ń ba a wí? Ó ti se ohun dídára fún mi. \v 7 Nígbà gbogbo ní ẹ̀yin ní tálákà pẹ̀lú yín, ẹ̀yin sì le se oore fún wọn nígbà tí ó bá wù yín, ṣùgbọ́n èmi ni ẹ̀yin kó ní nígbà gbogbo. \v 8 Ó ti ṣe èyí tí ó le ṣe: ó ti fi òróró kùn ara mi fún ìsìnkú mi. \v 9 Lótǐtó ni mo wí fun yín, níbikíbi tí a ó gbé wàásù ìhìnrere ní gbogbo aiyé, a ó sì sọ̀rọ̀ ohun tí obìnrín yǐ ṣe ní ìrántí rẹ̀.