adesinaabegunde_yo_mrk_text.../14/03.txt

1 line
568 B
Plaintext

\v 3 Nígbàtí Jésù wà ní Bẹ́tánì ní ilé Símónì adẹ́tẹ̀, bí ó ti jókǒ ní tábílì, obìnrin kan tí ó ní ìgò alabástà òróró iyebíye, tí ó jẹ́ aláìlábáwọn nérdì. Ó fọ́ ìgò náà ó sì dàá si ní orí. \v 4 Ṣùgbọ́n àwọn kan ń bínú. Wọ́n sì ń sọ̀rọ̀ láàrín ara wọn, wọn sì wípé, "Kí ni ìdí tí a se fi òróró yi sòfò? \v 5 A kò bá ti ta òróró ìkunra dídùn yí ní ọ̀dúńrún dénárì, kí á sí fún àwọn aláìní." Wọ́n sí bá obìnrin náà wí.