adesinaabegunde_yo_mrk_text.../13/11.txt

1 line
660 B
Plaintext

\v 11 Nígbàtí a bá mu yiń tí a sì jọ̀wọ́ yiń lọ́wọ́, ẹ má ṣe ṣàníyàn oun tí ẹ̀yin yíó sọ. Nítorí ní wákàtí náà, a ó fún yiń ní ọ̀rọ̀ tí ẹ̀yin yóò sọ; ki yíò jẹ́ ẹ̀yin ni yóò sọ̀rọ̀, bíkòṣe Ẹ̀mí Mímọ́. \v 12 Arákùnrin yóò jọ̀wọ́ arákùnrin fún ikú, àti bàbá yóò jọ̀wọ́ ọmọ rẹ̀ lọ́wọ́. Àwọn ọmọ yio dìde sí àwọn òbi wọn, nwọn yóò sì sọwọ́n di ẹni tí ikú npa. \v 13 Gbogbo ènìyàn ni yóò kórira yín nítorí orúkọ mi. Ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá forí tì í dópin, ẹni náà yóò yè.