adesinaabegunde_yo_mrk_text.../12/32.txt

1 line
566 B
Plaintext

\v 32 Olùkọ́ òfin náà dáhùn pé, “Olùkọ́, ìwọ sọ òtítọ́ pé Ọlọ́run kan ni ó wà, àti pé kò sí òmíràn lẹ́yìn rẹ̀. \v 33 Àti kí a fi gbogbo ọkàn, àti gbogbo òye, àti agbára fẹ́ ẹ, àti fẹ́ ọmọnìkejì ẹni bí ara ẹni, ó ju gbogbo ẹbọ sísun, àti ẹbọ lọ.” \v 34 Nígbà tí Jesu rí i dájú pé ó ti dáhùn pẹ̀lú òye, Ó wí fún un pé, “Ìwọ kò jìnà sí ìjọba Ọlọ́run.” Láti ìgbà náà lọ, ẹnikẹ́ni kò tún béèrè ohun kan lọ́wọ́ Jesu.