adesinaabegunde_yo_mrk_text.../12/13.txt

1 line
661 B
Plaintext

\v 13 NÍgbànáà ni wọ́n rán àwọn Farisí pẹ̀lú àwọn kan tí í ṣe ọmọ-ẹ̀yìn Herodu wá sọ́dọ̀ Jesu, láti fi ọ̀rọ̀ rẹ̀ mú. \v 14 Bí wọn ti dé, wọ́n wí pé: “Olùkọ́, àwa mọ̀ pé ìwọ máa ń sọ òtítọ́ láìsí ìbẹ̀rù ẹnikẹ́ni. Òtítọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ni ìwọ máa ń kọ́ni. Ńjẹ́ ó tọ́ tàbí kò tọ́ láti máa san owó orí fún Kesari?” Kí àwa kí ó san án, tàbí kí a máa san án? \v 15 Ṣùgbọ́n Jesu mọ ìwà àgàbàgebè wọn, Ó sì wí pé, “Èéṣe tí ẹ̀yin fi n dán mi wo? Ẹ mú owó idẹ kan wá kí n wò ó.”