1 line
511 B
Plaintext
1 line
511 B
Plaintext
\v 10 Tàbí ẹ̀yin kò ì tí ka ẹsẹ yìí nínú ìwé mímọ́? ‘Òkúta tí àwọn ọ̀mọ̀lé kọ̀sílẹ̀, òun náà ni ó di pàtàkì igun ilé. \v 11 Èyí wá láti ọdọ̀ Olúwa, ó sì jẹ́ ìyàlẹ́nu lójú tiwa’?” \v 12 Wọ́n ń wá ọnà láti mú Jesu, ṣùgbọ́n ẹ̀rù ń bà wọ́n nítorí ọ̀pọ̀ ènìyàn tó wà lọ́dọ̀ rẹ̀, nítorí tí wọ́n mọ̀ pé àwọn ló ń pòwe mọ́. Nítorí náà wọ́n fi í sílẹ̀ lọ. |