adesinaabegunde_yo_mrk_text.../12/01.txt

1 line
641 B
Plaintext

\c 12 \v 1 Nígbànáà ni Jésù bẹ̀rẹ̀ sí í fi òwe kọ́ wọn. Ó wípe, “Ọkùnrin kan gbin ọgbà àjàrà kan, Ó ṣe ọgbà yìí ká, ó sì wá ilẹ̀ fún ìfúntí wáìnì. Ó kọ́ ilé ìṣọ́, ó sì fi ṣe àgbàtọ́jú fún àwọn olùṣọ́gbà. Ó sì lọ sí ìrìnàjò. \v 2 Lákokò tí ó tọ́, ọkùnrin náà rán ọ̀kan nínú àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀ sí àwọn olùṣọ́gbà náà, kí ó gbà nínú èso ọgbà àjàrà náà lọ́wọ́ àwọn olùṣọ́gbà. \v 3 Ṣùgbọ́n wọ́n mú u, wọ̀n lù ú, wọ́n sì rán an padà lọ́wọ́ òfo.