\v 15 Lóòtọ́ ni mo sọ fún yín, ẹnikẹ́ni tí kò bá fẹ gba ìjọba Ọlọ́run bí ọmọ kékeré kan dájúdájú kò ní leè wọlé sí ibẹ̀." \v 16 Lẹ́yìn náà ó gbé àwọn ọmọ kékeré sí apáa rẹ̀ ó sì bùkún fún wọn bí ó se ńgbé ọwọ́ rẹ̀ lé wọn.