adesinaabegunde_yo_mrk_text.../09/20.txt

1 line
575 B
Plaintext

\v 20 Wọ́n mú ọmọkùnrin náà wá sọ́dọ̀ rẹ̀, nígbàtí ẹ̀mí náà rí Jésù, ó jẹ́ kí gììrì ki ọmọ náà lójijì. Ọmọkùnrin náà ṣubú lulẹ̀ ó sì ń pòfóló. \v 21 Jésù bá bi bàbá ọmọ náà, "Ó ti pẹ́ tó tí ti wà nírú ipò yìí?" Bàbá rẹ̀ dáhùn ówípé, "Láti ìgbà èwe rẹ̀ ni. Ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbà, \v 22 ó tilẹ̀ má n gbe jù sínú iná tàbí sínú omi láti paá lára nígbà míràn. Bí O bá le se ohun kóhun, sàánú fún wa kí o sì ràn wá lọ́wọ́."