adesinaabegunde_yo_mrk_text.../07/24.txt

1 line
585 B
Plaintext

\v 24 Ó sì dìde kúrò níbẹ̀, Ó sì lọ sí agbègbè Tírè àti Sídónì. Ó wọ inú ilé kan, kò sì fẹ́ kí ẹnikẹ́ni mọ̀ pé Òun wà níbẹ̀, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé kò le sápamọ́n fún wọn. \v 25 Ṣùgbọ́n lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, obìnrin kan tí ọmọ rè ní ẹ̀mí àìmọ́, gbọ́ nípa rẹ̀, ó wá, ó sì kúnlẹ̀ sílẹ̀ ní ibi ẹsẹ̀ rẹ̀. \v 26 Ara Gíríkì ni obìnrin náà ń se, ọmọ bíbí Sirofẹ́níkà níí se. Ó bẹ Jésù kí ó bá òun lé ẹ̀mí èsù inú ọmọbìnrin òun jáde.