adesinaabegunde_yo_mrk_text.../07/14.txt

1 line
508 B
Plaintext

\v 14 Ó tún pe ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn, Ó sì wí fún wọn pé, "Gbogbo ẹ̀yin ènìyàn ẹ tẹ́tí gbọ́ mi, kí òye kí ó sì yé yín. \v 15 Kòsí ohunkóhun láti òde àgọ́ ara ènìyàn tí ó le sọ ènìyàn di aláìmó nígbàtí ó báwọ inú ènìyàn. Bíkòse ohun tí ó jáde wá láti inú ènìyàn sí ìta ní ọ̀rọ̀ tàbí ní ìse, ni ó ń sọ ènìyàn di aláìmọ́." \v 16 "Bí ẹnikẹ́ni bá ní etí láti fi gbọ́, jẹ́ kí ó gbó."