\v 14 Nísinsìyí lẹ́yìn ìgbà tí a mú Johanu sínú ẹ̀wọ̀n, Jesu wá sí Galili, ó ń wàásù ìhìnrere ti Ọlọ́run. \v 15 Ó ń wí pé, “Àkókò náà dé wàyí, ìjọba Ọlọ́run kù sí dẹ̀dẹ̀. Ẹ yípadà kí ẹ sì gba ìhìnrere yìí gbọ́.”