\v 53 Wọ́n sì mú Jẹ́sù lọ ṣọ́dọ̀ olórí àlùfáà. Gbogbo àwọn olórí àlùfàà, àti àwọn àgbàgbà, àti àwọn akọ̀wé sì péjọ pẹ̀lú rẹ̀. \v 54 Pétérù sì n tọ̀ ọ́ lẹ́yìn ní òkèrè wọ̀ inú ilé, títí wọ́n fi dé àgbàlá olóri àlùfáà. Ó sì bá àwọn ẹ̀sọ́ jókǒ, tí wọ́n ń yáná.