\v 33 Lẹ́yìn náà ni wọ́n wá sí Kápánámù. Nígbàtí ó sì ti wọ sínú ilé kan, Ó biwọ́n léèrè pé, "Kíni ẹ̀yin n bá ara yín sọ lójú ọ̀nà.?" \v 34 Wọ́n sì dákẹ́ jẹ́ẹ́. Nítorítí wọ́n ti n ṣe àríyànjiyàn láàrin ara wọn níti ẹnití ó pọ̀jùlọ láàrin wọn. \v 35 Nígbàtí Ó jókòó, Ó pe àwọn méjìlá sí ọ̀dọ̀ ara rẹ̀ ó sì wí fún wọn pé, "bí ẹnikẹ́ni bá fẹ́ se ẹni àkọ́kọ́, Oun ni yíò jẹ́ ẹni ìkẹyìn àti ìránsẹ́ gbogbo ènìyàn."