\v 39 Ó pàṣẹ fún wọn pé kí wọ́n jókòó ní ìsòrí ìsòrí lórí koríko tútù. \v 40 Wọ́n sì jókòó ní ìṣọ̀rí ọgọ́rọ̀rún àti àràdọ́ta. \v 41 Ò sì mú ìsù àkàrà mǎrún àti ẹja méjì náà, ó gbójú sókè ọ̀run ó yà sí mímó ó sì fún àwọn ọmọ ẹ̀yin rẹ̀ pé kí wọn kí ó pín fún àwọn ènìyàn náà.